Web - Amazon

We provide Linux to the World


We support WINRAR [What is this] - [Download .exe file(s) for Windows]

CLASSICISTRANIERI HOME PAGE - YOUTUBE CHANNEL
SITEMAP
Audiobooks by Valerio Di Stefano: Single Download - Complete Download [TAR] [WIM] [ZIP] [RAR] - Alphabetical Download  [TAR] [WIM] [ZIP] [RAR] - Download Instructions

Make a donation: IBAN: IT36M0708677020000000008016 - BIC/SWIFT:  ICRAITRRU60 - VALERIO DI STEFANO or
Privacy Policy Cookie Policy Terms and Conditions
Folklore - Wikipedia

Folklore

From Wikipedia

Yoruba Folklore

Contents

[edit] Oju-iwe Kiini

Yoruba Folklore

Ijapa Tiroko Oko Yannibo

Olagoke Ojo

Ojo


==Yorùbá Literature: A Review of Ìjápá Tìrókò Ọkọ Yánníbo by Ọlágòkè Òjó published by Longman Nigeria PLC, Lagos, Nigeria in 1973. Àỵèwò Ìwé Ìjápá Tìrókò Ọkọ Yánníbo tí Ọlágòkè Òjó se. Ogún ni ìtàn tí ó wà nínú ìwé yìí==

[edit] 1 Ìjàpá àti Àtíòro

Ìtàn ní Sókí

Ìtàn yìí, dá lé orí Ìjàpá àti Àtíòro. Ìyàn mú púpò ní ìlú Ìjàpá. Ó to Àtíòro tí ó ń rí oúnje je lo. Àtíòro mú Ìjàpá lo sí orí òpé tí ó ti máa ń rí oúnje je. Nígbà tí won dé ibè, wón jeun, Àtíòro so pé ilé yá, Ìjàpá kò, Àtíòro sì fi sílè níbè. Nígbà tí Ìjàpá se tán láti padà sílé, ó puró gba ìyé lówó àwon eye. Ìyé yìí ni ó fi ń fò bò nílé tí ó fi já sínú odò. Ònì ríi, ó fé pa á je. Ìjàpá puró pé òun yóò bá Ònì ko ilà fún àwon omo rè. Ó pa gbogbo omo Ònì je tán. Ibi tí Ònì náà ti ń lé e láti pe á ó dá ogbón sun Ònì ní iná. Òkú Ònì tí ó ń rù lo ni ó pàdé Ekùn lónà. Ekùn fé gbà eran Ònì lówó rè sùgbón Ìjàpá fi ogbón so irun Ekùn mó igi. Ìgbín tú Ekùn sílè. Ekùn tún rí Ìjàpá, ó fó Ìjàpá mó òkútà. Aáyán àti Eèrà nì ó sa Ìjàpá jo kí ìkámùdù tó wá bá a dán èyìn rè tó bí ó se wà lónìí yìí.

Àwon Èdá-ìtàn

Ìjàpá: Ó lo bá Àtíòro pé kí ó mú òun lo sí ibi tí ó ti ń rí oúnje je bí ìyàn ti mú tó ní ìlú won Àtíòro: Òun ni ó gbé Ìjàpá lo sí orí òpe tí ó ti ń rí eyìn je Yánníbo: Ìyàwó Ìjàpá. Ìjàpá kò so fún un pé òun ń bá Àtíòro lo sí ibì kankan kí ó má baà lo ba je nínú oúnje tí ó máa rí níbè Àkùko: Ìjàpá ni ó lo ko légbèé ilé Àtíòro kí Àtíòro bàa rò pé ilè ti mó Elému: Ìpàpá ni ó kó agbè kórùn tí ó se bí elému kí Àtíòro bàa rò pé ilè ti mó, àwon elému ti ń lo sí oko. Elékòo: Ìjàpá náà ni ó ń palówó èko pé ipáába èko ó légbèé ilé Àtíòro kí Àtíòro bàa rò pé ilè ti mó kí wón lè tètè lo sí ibi tí oúnje wà tí wón ń lo Odo ńlá: Àtíòro gbé Ìjàpá kojá odò yìí nígbà tí wón ń lo sí ibi tí wón ti fé lo jeun. Odò yìí ni Ìjàpá ja bó sí nígbà tí ó ń dánìkan bò nílé Eku Àgó: Níbi tí Ìjàpá ti ń je eyìn ní orí òpeni ó ti rí eku yìí. Ìjàpá pa á ó sì so ó sí àpò Ònì: Òun ni ó fé pa Ìjàpá je nígbà tí ó já bó sí inú odò. Ìjàpá so pé kí ó má pa òun pé òun lè bá a ko ilà fún àwon omo rè bí òun se ko ilà fún eku Àgó. Ó fi eku náà hàn án Oba: Nígbà tí Ìjàpá fé padà sí ilé léyìn ìgbà tí Àtíòro ti fi sílè lórí òpeni ó bá pe àwon eye jo. Ó ní Oba ló ní kí òun lo wo àlàáfíà won wá. Ó ní kí wón dá ìyé fún òun kí òun fi padà sí ilé Eye Òpéère: Òun ni ó dúpé lówó Ìjàpá lórúko àwon eye yòókù. Atuko : Adití atukò ni ó gbé Ìjàpá kúrò ní òdó Ònì. Olóóla: Eni tí ó máa ń kolà fúnmi Ìjàpá ni ó pa ara rè ní Olóólà fún Ònì. Alákàn: Òun ni Ìjàpá sá sí ihò rè nígbà tí Ònì fé mú un. Iná tí Òní dá láti fi lé Ìjàpá jáde nínú ihò yìí ní Ìjàpá padà wá fi sun Ònì jinná. Àgbònrín: Òkan nínú àwon eranko tí Ìjàpá pàdé lónà nígbà tí ó ń ru òkú Ònì lo. Ìjàpá puró fún àgbònrín pé òkú ìyá òun ni òún rù. Kò jé kí àwon eranko yìí se ìrànlówó fún òun nípa òkú tí ó pè ní ti ìyá rè yí. Ekùn: Òun ni ó fi agbára mú Ìjàpá láti tú ohun tí ó pè ní òkú ìyá òun tí ó sì bá eran Ònì níbè. Ekùn gba eran Ònì yìí sùgbón kí ó tó je é, Ìjàpá puró fún un pé òun fé bá a di irun, ó di irun rè mó igi ó sì eran Ònì je tán lójú Ekùn. Etu: Ekùn bè é pé kí ó tú òun sílè. Kò túu sílè. Ó ní yóò pa òun Ológèdé: Òun náà kò láti tú Ekùn sílè. Ìgbín: Òun ni ó ti Ekùn sílè. Ekùn fi pamó sí abé ìràwé kí àwon ènìyàn má baà rí i pa. Láti ojó yìí ni ó ti ń gbé abé ìràwé. Ìyá Arúgbó: Òun ni ó pàdé Ekùn lónà tí ó tí ó sì so fún Ekùn pé rírì mó inú àbàtà kò lè pa Ìjàpá bí ó tilè ń yo ìdin. Òun ni ó so fún Ekùn pé kí ó fó Ìjàpá mó orí àpáta Aáyán àti Eèrà: Àwon ni wón sa Ìjàpá jo léyìn ìgbà tí Ekùn ti fó o mólè tán Ikamùdù: Òun ni ó fé dán èyìn Ìjàpá léyìn ìgbà tí Aáyán àti Eèrà ti sà á jo tán. Rírùn tí ó so pé Ìkamùdù ń rùn ni kò jé kí ó bá a dán èyìn rè mó. Èyí ni ó jé kí èyìn Ìjàpá rí Kúdakùsa.


[edit] 2 Ode, Ará-òrun àti Ìjàpá

Ìtàn ní Sókí Ìtàn yìí dá lé orí ode kan. Ode yìí lóògùn. Gbogbo eranko burúkú inú igbó ni ó ti parun tán. Èyí ni ó wá mú kí ó bèrè síí máa pa eye. Ní ojó kan ó ta ìbon mó eye Òrofó kan. Ó rò pé eye yìí ti kú ni sùgbón eye náà kò kú, ó sá lo. Ibi tí ó ti ń wá eye yìí ni ó ti dé òdò àwon Ará-òrun. Wón ní kí ó wá máa dá emu fún àwon sùgbón kò gbodò dúró wo àwon tí ó bá ti gbé emu náà sílè. Ó se èyí fún ìgbà pípé kí ó tó wá rè é ní ojó kan. Ó be Ìjàpá kí ó bá òun gbé emu lo sùgbón Ìjàpá dúró wo àwon Ará-òrun. Inú bí won. Wón lé Ìjàpá, won kò rí i mú. Nígbà tí Ode padà dé, wón bá a fi ìjà pa eéta. Ó ségun won. Léyìn èyí ni àwon Ará-òrun tó so ohun tí ó se fún un. Ó sàlàyé pé Ìjàpá ni ó dúrò wò wón kì í se òun. Wón dárí jì í ó sì bèrè síí gbé emu rè lo sódò won ó sì ti ipa èyí di Olówó tabua.


Àwon Èdá-ìtàn àti Àwon Ohun tí ó se Kókó nínú Ìtàn Òrófó: Eye tí Odé yan ìbon sí tí kò kú tán tí atégùn fé sí tí ó sì fò lo. Ode: Òun ni ó pa gbogbo eran inú igbó tán tí ó wá bèrè sí fé máa pa eye. Òrófó tí ó ta ìbon mó jí Ibi tí ó ti ń wá a lo ni ó ti sonù sí inú igbó tí ó ti di eni tí ó lo ń dá emu fún àwon Agbada: Ibè ni àwon Ará-òrun ní kí ó máa da emu sí. Pón-ùn márùn-ún ni ó ń gbà fún èkún agbada emu. Àwon Obìnrin: Wón ní àwon yóò máa bá Ode ru emu sùgbón kò gbà fún won. Ìjàpá: Òun ni ó ń bá Ode gbé emu lo fún àwon Ará-òrun nígbà tí sòbìà mú Ode. Ìjàpá dalè, ó dúró wo àsírí àwon Ará-òrun. Àwon Ará-òrun fé mú un, won kò rí i mú. Nígbà tí ó dé ilé, ó puró fún Ode pé àwon jàgùdà ni ó dá òun lónà tí ó jé kí òun pé. Àwon Ará-òrun: Àwon ni ó sánú ode tí wón ní kí ó wá máa dá emu fún àwon tí wón sì ń fún un ní owó. Wón kilo fún ode pé kí ó kàn máa gbé emu sílè ni o kí ó má dúró láti wo àwon. O se báyìí fún ìgbà pípé títí di ìgbà tí ara rè kò fi ya tí ó fi be Ìjàpá kí ó máa bá òun gbé emu lo fún won. Ìjàpá lo gbé emu fún won sùgbón ó dúrò wo àwon ará òrun. Àwon ará-òrun lé e, won kò rí i mú. Nígbà tí Odé padà dé, àwon ará-òrun bá a jà gidi ni sùgbón ó ségun won. Léyìn ìgbà tí agbára won kò ká a yìí ni wón tó so ìdí tí wón fi bá a jà fún un, ó sì toro àforíjì. Wón dárí jì í. Ó ń ta emu rè lo ó sì di Olówó

[edit] 3 Ìjàpá àti Omobìnrin Oba

Ìtàn ní Sókí Ìtàn yìí dá lé orí Oba kan tí ó fé fi omobìnrin rè fún oko tí ó wá so fún àwon okùnrin pé kí wón wá se ìdíje ebè kíko tí ó sì so pé eni tí ó bá borí ni òun yóò fi omobìnrin òun fún. Lára àwon tí ó kópa nínú ìdíje yìí ni Ìjàpá, Ekùn àti Kannakánná. Ìtàn yìí kò fi agbára kógo járí nítorí pé nígbà tí a ó fi dé òpin ìtàn, a kò gbo nnkan kan nípa omobìnrin oba mo a kò sì mo eni tí omobìnrin oba já mó lówó.

Àwon Edá-ìtàn Omobìnrin Oba: Òun ni gbogbo ènìyàn àti eranko nífèé láti fé. Ìjàpá: Òun náà wà lára àwon tí ó fé fé omobìnrin oba. Ó gbé omobìnrin yìí sá lo sú inú igi. Alákàn so àsírí yìí fún Ekùn. Ekùn gbé omo yìí lo sí ilé rè. Ìjàpá dá ogbón pa Ekùn. oba sì dá ilé àti ònà rè sí méjì, ó kó o fún Ìjàpá. Ekùn: Ó wà lára àwon tí ó fé fi omobìnrin oba se ìyàwó. Òun ni ó ń pe ofò kí okó kannakánná máa ya. Òun ni ó lo jí omobìnrin oba gbé níbi ojú rè méjèèjì kí ó tó pa á. Kannakánná: Òun náà fé fé omobìnrin oba. Òun ni máa ń saájú nínú ebè kíko tí Ekùn ń pofò kí okó rè lè ya. Ìyá arúgbó kan ni ó fon ikun sí ara okó rè tí okó rè kò fi ya mó. Alákàn: Òun ni ó fi àsírí ibi tí Ìjàpá gbé omobìnrin oba pamó sí han Ekùn. Ìrè: Ìrè ni Ìjàpá dín tí ó ń je tí ó pà ní ojú ara rè. Ìrè díndín tí ó fún Ekùn je ni ó fi ráyè yo ojú Ekùn tí ó sì pa á. Àsá: Àsá ni ó rí Ìjàpá níbi tí ó ti ń pa Ekùn tí ó lo puró fún Oba pé òun ni òun pa á. Nígbèyìn, ó jéwó fún Oba pé kìí se òun ni òun pa Ekùn. Yánníbo: Òun ni ó lo gbé Ìjàpá tí a dì sínú ewé lo fún Àsá tí ó pè é ní obì. Ó ní Ìjàpá ní kí Àsá bá òun gbé obì náà pamó. Inú ewé yìí ni Ìjàpá ti gbó àsírí tí Àsá fi enu ara rè tú síta pé òun kó ni òun pa Ekun. Ìyàwó Àsá: Òun ni oko rè so pé kí ó dé òun mó inu akèngbè kí ó lo gbé òun fún Ìjàpá tí Ìjàpá fir í Àsá pa je.


[edit] 4 Àwon Eye àti Ìjàpá

Ìtàn ní Sókí Ìtàn yìí dá lé orí Ìjàpá tí ó fé dara pò mó àwon eye nítorí àsè tí wón máań se fún ara won. Léyìn òpòlopò ìpè, àwon eyé gba Ìjàpá láyè láti dara pò mó won. Kò ni Ìjàpá lára láti lo sí ibi àsè tí Eyelé pè nítorí pé orí ilè ni ó ń gbé. Ogbón ni Ìjàpá dá láti lo sí ibi àsè àgbìgbò, ogbón náà ni ó sì fi padà. Ìtàn yìí fi ogbón èwé Ìjàpá hàn.

Àwon Èdá-ìtàn Ìjàpá: Òun ní o dara pò mó àwon eye kí ó lè ráyè máa lo sí ibi àsè won. Kò sí wàhálà, fún un láti lo sí ibi àsè Eyelé sùgbón nígbà ó kan àsè ibi ìkómojáde Ògbìgbò, ó ní kí Yámníbo di òun sínú ewé kí ó sì fi òun rán ìyàwó Ògbìgbò pé obì ti òun fit a á lóre ni ó wà níbè. Báyìí ni Ìjàpá se dá ogbón lo sí àsè Ògbìgbò. Nígbà tí ó ń bò, o ní kí Ògbìgbò jé kí àwon se orò kan. kí ó kí owó bo ìrán ìdí òun kí òun náà ki owó bò ó lénu. Ó ní orò yìí ni yóò jé kí omo rè ye. Àgbìgbò se, bí ó se so, Ìjàpá kò sì jé kí ó yo owó re àfi ìgbà tí ó tó gbé e padà sí orí ilè. Yánníbo: Òun ni Ìjàpá fi ‘obi’ iró rán sí Àgbìgbò. Ìjàpá di ara rè sí inú ewé ó pè é ní obì. Awon Ìyàwó Àgbìgbò: Méta ni wó. Òkán bímo, òkán wa ra nnkanlójà, èkéta sì ń dáná oúnje àsè ìkómojáde. Eyelé: Òun ni Ìjàpá lo fi ìròrùn je àsè ní ilé rè Àgbìgbò: Ogbón èwé ni Ìjàpá fi lo je àsè ní ilé rè, ogbón èwe náà ni ó sì fi padà.

[edit] 5 Ìjàpá àti Àwon Eranko

Ìtàn ní Sókí Àwon eranko kò rí omi mu. Wón gbìmò pò láti gbé omi tí ó jinlè kan tí gbogbo won yóò máa mu. Ìjàpá kò bá won gbé níbè. Nígbà tí wón gbé e tán, Ìjàpá bèrè síí fi orin, ‘Ma bÉrin lódò ma tè é’ dérù bà wón tí ó sì ń lé won sá kúrò létí odò tí òun nìkan sì ń dá omi mu. Ó se, àwon eranko gbé ère ènìyàn kan tí wón fi àtè ra lára tí wón rì mó ònà odò yìí. Ibi tí Ìjàpá ti ń na ère yìí ni gbogbo ara rè ti lè mó on. Ibi tí àwon eranko ti ń dábàá àti fi ìyà je é ni wón rí i tí ó ń ta ìdin jáde. Wón rò pé ó ti kú ni wón sì gbé e jù sí inú igbó. Ìdí nìyí tí Ìjàpá fi ń gbé abé ìràwé ní inú aginjù.

Àwon Èdá-ìtàn Ìjàpá: Òun ni ó bínú ní ìpàdé àwon eranko nítorí pé won kò fi je alága. Kò bá won gbé omi síbè, ó ń dá ogbón mu omi. Wón dá ogbón fi ère ènìyàn tí ó ní àtè lára mú un síbè, àwon eranko kò rí àyè fi ìyà je é. Ehoro: Òun ni oríkì rè ń jé ‘Ò-gbékèlésè fowó elésin ná’. Òun ni ó kéde ìpàdé fún gbogbo eranko. Kìnìún: Òun ni wón fi se alága àwon eranko. Ó kò láti dánìkan só omi tí Ìjàpá ń fi ogbón èwé mu nítorí pé òun ni oba. Ekùn: Òun ni igbákejì alága Erin: Òun ni Baálè àwon eranko. Òun náà kò láti dánìkan só omi. Àgbònrín: Òun ni ó dábàá pé kí won rú ebo nítorí omi tí ó wón won. Ekùn náà kín in léyìn. Òun náà ni Etu dámòràn pé kí ó lo bá ohun abàmì tí ó ń dà wón láàmú jà tí ó kò Òkété: Òun ló dábàá pé kí won gbé odò tí ó jìn. Òun àti Ikún ni ó sì saájú won nínú isé yìí Òyà: Òun ni ó dábàá pé kí Kìnìún lo bá ohun abàmì jà tí Kìnìún kò nítorí pé òun ni oba. Túùpú: Òun ni ó dábàá pé kí erin lo bá ohun abàmù jà tí Erín kò. Ehoro: Òun ni wón ní kí ó gbé igi ni ère rè. Ère yìí ni wón fi mú Ìjàpá Omodé: Ère tí Ehoro gbé ni Ìjàpá ń pè ní Omodé.

[edit] 6 Àjá àti Ìjàpá

Ìtàn ní Sókí Ìjàpá ni ó lo bá Ajá pé kí ó mú òun lo sí ibi tí ó ti máa ń rí oúnje je. Ajá mú Ìjàpá lo sí oko Olóko tí ó ti máa ń jí isu wà. Ajá wa isu tí ó mo ní ìwòn sùgbó Ìjàpá wa isu ti apá rè kò níí ká. Olóko rí Ìjàpá mú. Ìjàpá so pé Ajá ni ó jalè. Ó mú olóko lo sí ilé Ajá. Won kò bá Ajá nílé sùgbón wón lo fi ejó rè sun oba. Nígbà tí wón wá mú Ajá, o díbón pé ara òun kò yá. Ó fó eyin méjì tí ó ti fi sí enu mólè níwájú oba. Oba gbà pé òótó ni ara Ajá kò yá, ó sì dá a sílè. Láti ojóyìí ni olóko ti máa ń de tàkúté sí oko rè láti lè fi mú eni tí ó máa ń jí isu rè wà.

Àwon Èdá-ìtàn

Àwon èdá-ìtàn tí ó se pàtàkì ni a ti ménu bà ní sókí, ìyen Ìjàpà Ajá àti Oba. 

Orin Orin tí Ìjàpá ń ko nígbà tí ó ń ru isu bò láti oko ni, ‘Ajá o, Ajá o, ràn mí lerù- Jáláńká-toofé”.

[edit] 7 Ìjàpá àti Òrò-Ìrókò

Ìtàn ní Sókí Ìjàpá ni ó lo bá Òrò-Ìrókò pé kí ó fún òun ní isu méjò kí ó sì wá lu òun ní kùmò méjì dípò rè. Bí Ìjàpá se ń lo sí ilé ni ó pàdé Òyà. Ó mú Òyà lo sí ilé. Léyìn ìgbà tí won jiyán tán, ó ní kí Òyà sùn ní enu ònà. Òyà ni Òrò-Ìrókò lò ní kùmò méjì dípò Ìjàpá. Òyà sì kú. Báyìí ni Ìjàpá se se sí àwon eranko mìíràn tí òun àti eranko náà sì ń fi òkú eran tí ó bá ti kú je iyán. Nígbà tí ó kan Ìgbín, Ìgbín ran lo. Ìjàpá wá dá ogbón ta òwú tín-ín-rín mó okèngbè. Òrò-Ìrókò fi akèngbè pe Ìjàpá, ó lu akèngbè fó sùgbón ní ojó kejì, ni Ìjàpá tún yo sí Òrò-Ìrókò. Èrù ba Òrò-Ìròkò. Ó wá rí i pé owó òun kò lè ká Ìjàpá, àwon méjèèjì sì di òré kòríkòsùn.

Àwon Èdá-ìtàn Ìjàpá: Òun ni ó lo ń gba isu lówó Òrò-Ìrókò Òrò-Ìrókò: Òun ni ó gbà láti máa fún Ìjàpá ní isu méjì méjì kí ó sì máa lù í ní kùmò méjì méjì dípò isu yìí Òyà: Òun ni Òrò-Ìròkò kókó lù pa dípò Ìjàpá léyìn ìgbà tí òun àti Ìjàpá ti fi isu Òrò-Ìrókò je iyán tán tí ó sì sùn sí enu ònà. Òkété: Léyìn ìgbà tí òun òun àti Ìjàpá ti fi eran Òyà je iyán tán ni Òrò-Ìròkò lù ú pa ní enu ònà tí ó sùn sí Etu: Léyìn ìgbà ti òun àti Ìjàpá ti fi eran Òkété je iyán tan tí ó sì sùn sí enu ònà ni Òrò-Ìrókò fi kùmò lù ú pa Ìgbín: Léyìn tí òun àti Ìjàpá ti fi eran Etu je je iyán tan ni ó ti ràn gun igi lo. Eléyìí ni kò jé kí Òrò-Ìròkò rí i pa.


[edit] 8 Eyelé àti Ìjàpá

Òré nì Ìjàpá àti Eyelé. Òpò ìgbà ni Ìjàpá máa ré Eyelé je ti Eyelé máa ń fi ara dà á. Ó se ní ojó kan, Ìjàpá bá Eyelé lo sí ilé àna rè. Ní òhún, Ìjàpá fi òkánjúa jeun níbè. Bàbá Ìyàwó Eyelé pinnu láti ta wón lóre. Ó so àkúgbó okùn mó esin tí ó ti tì mó inú yàrá lórùn, okùn yìí sì wà ní ìta. Ó so okùn tuntun mó àgbò lórùn. Inú yàrá náà nì ó ti àgbòmó. Ó ní kí Eyelé àti Ìjàpá mú won ní òkòòkan. Ìjàpá fi òkánjúà mú okùn tuntun láìmò pé àgbò ni wón so ó mó lórùn. Eyelé mú okùn àkúgbó tí wón so mó esin lórùn. Nígbà tí wón ń lo sí ilé Eyelé ta lé orí esin rè, esin ń lo fe fe fe. Ìjàpá náa gun àgbò rè sùgbón àgbò kò lè sáré. Ó se Ìjàpá fi ìbínú pa àgbò, ó tún dá ogbón èwé, ó jé kí Eyelé pa esin tirè náà. Ogbón burúkú náà ni Ìjàpá dá tí ó fi gba gbogbo eran esin lówó Eyelé nípa síso fún un pé eran tí ó ba fi òbe òun gé tí ó dún ‘pébé’ jé ti òun Ìjàpá tí ó ni òbe tí wón fi pa esin. Èyí tí ó bá dún ‘kìdìrì’ni ti Eyelé. Báyìí ni Ìjàpá se gba gbogbo eran esin tí ó gbé orí fún Eyelé. Eyelé rí orí esin mólè, ó yo ojú rè méjèèjì sí ìta. Èyí dá èrù ba Ìjàpá. Ó da gbogbo eran owó rè sílè láti lo so fún oba pé òun rí ibi tí ilè ti lójú. Nígbà tí Ìjàpá ti lo tán, Eyelé yo orí esin ó sì kó gbogbo eran yòóku lo si ilé. Oba bá Ìjàpá wá sí ibi tí ó ti so pé ilè lójú sùgbón won kò bá nnkan ní ibè mo. Oba fi ìyà je Ìjàpá nípa rírì í mó ilè. Ìjàpá yo jáde sá nígbà tí Obá lo tán. Ìtàn yìí kó wa pe kí a má máa se ojú kòkùrò.

Àwon Èdá-Ìtàn Ìjàpá àti Eyelé ni àwon èdá-ìtàn tí ó se pàtàkì. Àwon mìíràn tí wón tún menu bà ni ìyàwó àfésónà Eyelé àti bàbá re. Wón tún sòrò nípa oba àti àwon onílù nínú ìtàn náà.

Orin Orin tí wón ko nínú ìtàn yìí ni, “Mo ríbi ilè gbé lójú ----------ilè”


[edit] 9 Ìjàpá àti Omo-Alákàrà

Ní ìgbà kan, ìyá alákàrà kan wà tí ó máa ń dín àkàrà ní etí ilé Ìjàpá. Ìjàpá fé je nínú àkàrà yìí sùgbón kò ní owó lówó. Ó wá dá ogbón láti lo máa korin ní ojú ònà ibi tí omo àlàkàrà máa ń gbà lo ta àkàrà re pé, “Oníràwé mo gbònà….Torofínní tofínní”. Omo alákàrà gbó, ó gbé àkàrà jù sílè, ó bèrè síí jó. Ìjàpá gbé ìgbá àkàrà, ó lo je gbogbo àkàrà inú rè. Ìyá alákàrà náà tèlé omo rè wá sí ibè, ijó ni òun àti omo rè bèrè síí jó nígbà tí ó gbó orin Ìjàpá. Oba ìlú pàápàá dé ibè, ó fi ijó bé e títí tí adé rè fi sí dànù. Òsanyàn elésè kan ni ó wa tèlé won tí ó wá rí Ìjàpá mú nítorí pé kò jó ní tirè. Gégé bí ìse rè, Ìjàpá ká owó àti esè wonú, ó bèrè síí se ìdi. Òsanyìn se bí ó ti kú ni. Ó fi sílè. Ó wá wow o igbo lo.

Àwon Èlá-ìtàn Ìjàpá omo alákàrà ìyá alákàrà, oba àti òsanyìn elésè kan ni àwon èdá-ìtàn tí ó se kókó.


[edit] 10 Adígbónránkú, Ekùn, Ajá àti Ìjàpá

Ní ìgbà kan, ebi ń pa Ìjàpá. Láti lè rí oúnje je, ó be Adígbónránkú lówè pé kí ó lo ná èko ní ìnákúùná lódò ìyá eléko lójà. Bí ìya eléko bá ti fi ìbínú nà án kí ó dákú. Adígbónránkú sì se béè. Ìjàpá so pé àbúrò òun ni Adígbónránkú àti pé kí ó tó lè jí, ìyá eléko gbódò gbé òpòlopò oúnje lo sí ilé òun. Ìyá eléko se béè Ìjàpá sì jí Adígbónránkú. Léyìn tí Adígbónránkú ti jí, ó wá bá Ìjàpá kí ó pín òun ní òúnje tòun. Ìjàpá kò jálè. Adígbónránkú sì lo fi ejó re sun Ekùn. Ekùn móra láti wá pa Ìjàpá sùgbón Ìjàpá puró fún un pé tEkùn ni gbogbo oúnje náà sùgbón kí ó tó lè kó o lo, òkòòkan àwon gbódò se orò kan. Orò náà ni síso okùn mó ara àwon lórùn mó igi ìrókò. Báyìí ni Ìjàpá se so orùn Ekùn mó igi ìrókò tí ó sì pa á. Léyìn ìgbà tí Ìjàpá ti se eran Ekùn sílé tán, ó lo fi ewìrì Ajá ní ìsò àgbède so pé òun ti se eran Ekùn sílé. Ajá gbó, ó lo gba eran lówó Yánníbo nílé ó sì je é. Òun náà sì tún wá ń fi ewìrì so pé òun ti je eran Ekùn tán. Ìjàpá sáré lo sí ilé. Nígbà tí ó gbó pé Ajá ti je eran Ekùn, ó padà sí ìsò agbède Ajá ó sì fi iringbígbóná bo ajá nímú. Ìdí nì yí tí imú Ajá fi di dúdú

Orin Ìjàpá: mo ní sìnkìn nílé………Sìnkùn Ajá: mo jé é tan, mo jé é tán ……….Porongodo

[edit] Oju-iwe Keji

Àwon Èdá-ìtàn Ìjàpá: Òun ni ó so fúnm Adígbónránkú pé kí ó ná èko ní ìnákúùnà, kí ó sì dákú bí ìyá déko bá ti nà án. Òun ni ó fi ogbón èwé jí Adígbónránkú. Òun ni kò fún Adígbónránkú lára oúnje tí ìyá eléko gbé fún un. Òun ni ó fi ogbón èwé pa Ekùn tí ó lo fi ewìrì ko orin nípa eran Ekùn tí ó sè sílé. Òun ni ó fi irin gbígbóná jó Ajá nímú. Adígbónránkú: Òun ni ó ná èko ní ìnákúùná tí ó sì díbón pé òun kú nígbà tí ìyá èléko nà án. Òun ni Ìjàpá kò fún lára oúnje tí ìyá eléko kó fún Ìjàpá. Òun ni ó fi ejó Ìjàpá sun Ekù Ekùn: Òun ni Adígbónránkú fi ejó Ìjàpá sùn. Òun ni Ìjàpá so orùn rè mó igi ìrókò títí tí ó fi kú tí Ìjàpá sì se eran rè. Ajá: Òun ni ó lo gba eran Ekùn lówó Yánníbo tí ó sì je é. Òun ni ó fi ewìrì ko orin pé òun je eran Ekùn. Òun ni Ìjàpá fi irin jó ní imú tí imú rè fid i dúdú di òní.

[edit] 11 Ìjàpá àti Yánníbo

Ìtàn ní Sókí Yánníbo be oko rè Ìjàpá pé kí ó yé lo máa jí isu wà ní oko olóko mó pé kí òun náà máa gbin isu fúnra rè. Ìjàpá bèèrè owó tí òun yóò fi ra èbù, Yánníbo fún wa ní pónùn márùn-ún pé kí ó fir a egbèrún èbù sùgbón dípò egbèrún, èédégèta ni Ìjàpá rà ní pónùn méjì tí ó sì da pónùn méta sí àpò. Ìjàpá kò fún àwon tí ó bá a se isé oko rè ní owó isé won. Nígbà tí isu náà ta dáadáa tán, ó wà á wálé, Yánníbo sì fi gún iyán. Ìjàpá so pé àfi tí kYánníbo bá mo orúko isu òun ni ó tó lè je nínú iyán náà. Léyìn òpòlopò ojó tí Yánníbo kò ti je nínú iyán yìí ni ó bá to, ìgbín lo pé lá ó kó òun lógbón. Ìgbín kó o lógbón pékí ó ra òpòlopò ilá kí ó dà á sí ònà tí Ìjàpá máa ń ru isu gbà. Yánníbo se béè. Ibi tí Ìjàpá ti ń ru isu bò ni ó tit e ilá mólè tí ó subú tí àwon isu rè sì dá. Ibi tí ó ti ń sa àwon isu yìí ni ó ti dárúko won tí ó pè wón ní Lásinrín àti Tètèègún. Báyìí ni Yánníbo se gbó orúko àwon isu yìí níbi tí ó fi ara pamó sí. Ó so ó fún oko rè nígbà tí ó bèèrè, ó sì ráyè bá a je iyán àti obè adìye tí ó sè ní ojó máà. Báyìí ni Ìgbín se yo Yánníbo nínú ìwà aláìláàánú ti oko rè ń hù

Àwon Èdá-ìtàn Ìjàpá: Òun ìyàwó rè rò pé kí ó máa gbin isu tí ó gbìn ín tán tí kò sì fé kí ìyàwó je nínú iyán tí wón fi isu náà gún Yánníbo: Òun ni ó fún oko rè ní owó tí ó fi ra èbù isu tí isu tat í wón fi gúnyán tí oko rè kò fé kó je nínú iyán náà Ìgbín: Òun ni ó kó Yánníbo lógbón tí ó fi ráyè je nínú iyán tí wón gún tí oko maań dánìkan je télè Aláàárù àti Alágbàse: Àwon ni ó bá Ìjàpá ru isu tí wón sì bá a sisé ní oko sùgbón tí Ìjàpá kò san owó òyá won fún won.

[edit] 12 Ìgbín àti Ìjàpá

Ìgbín àti Ìjàpá jo ń de èbìtì. Òkánjúà kò jé kí Ìjàpá fé gba eran kékeré tí èbìtì mú nútorí pé àdéhùn ni pé bí eni kan bá gba eran tí èbìtì mí ní ojó kan, eni kejì ni yóò gba ti ojó kejì. Nígbà tí ó pa eku, ìgbín so fún Ìjàpá pé òkété ni yóò mú ní ojó kejì, Ìjàpá fún Ìgbín ní eku, ó ń dúró de òkété. Nígbà tí ó mú òkété, Ìjàpá tún fún Ìgbín ó tún ń dúró de òyà. Báyìí ni Ìjàpá ń se tí kò rí nnkan kan mú lo sí ilé ti Ìgbín sì ń gbé eku, òkété òyà, túùpù àti àgbònrín lo sílé. Gégé bí ise rè Ìgbín tún so pé Èèmò ni èbìtì yóò mú léyìn àgbònrín. Ìjàpá rò pé Èèmò gbódò tóbi ju àgbònrín lo, ó gbé àgbònrín fún Ì`gbín ó ń dúró de Èèmò. Lóòóto, Èèmò ni èbìtì mú ní ojó yìí. Ìgbín kò wá, Ìjàpá nìkán ni ó wá. Èèmò yìí fi ojú Ìjàpá rí. Ó ní kí ó máa ru òun lo sí àárín ìlú. Nígbà tí Ìjàpá kò fé se èyí ó ní kí ojú Ìjàpá di òbérékété. Léyìn ìgbà tí Ìjàpá tó gbá láti gbé e niojú rè tó là. Ó sì ní kí Ìjàpá máa korin pé “Mo gbéèmò dé--- Èèmò”. Nígbà tí ó gbé Èèmò dé ààfin tí oba ní kí ó gbe e padà, ó ní kí ojú oba fó. Ó ní kí oba fún òun nílé. Ìjàpá ni ó sì ń se wàhálà láti tójú Èèmò yìí. Léyìn ìgbà tí oba ti ké gbààjarè pé kí wón gba òun. Ìgbín náà ni ó gbà láti ran oba lówó. Ó gbé emu wá fún Èèmò èyí tí Èèmò ní kí Ìjàpá máa gbé sí òun lénu. Ó mu emu yó, Ìgbín so fún oba pé kí ó wá àwon géńdé tí yóò jó o mole. Wón jó o pátápátá. Léyìn tí ó ti jóná tán ni Ìjàpá wá mú òpá tí ó fi ń lù eérú rè tí ó sì ń korin pé, “Eérú ìkà rèé…. Ìkà”. Eérú tí ó fé sí Ìjàpá ní imú ni ó fid i aránmú.

Àwon Èdá-ìtàn Ìjàpá: Òun àti Ìgbín ni won jo ń de èbìtì kí ó tó fi òkánjúà gbé Èèmò wálé Ìgbín: Wón ní gbogbo ogbón tí alábaun ní, èyìn ló fi ń to ìgbín. Ogbón ni Ìgbín fi gbé gbogbo eran tí wón pa lo ilé tí ó sì fi Èèmò sílè fún Ìjàpá. Àwon eran tí Ìgbín gbé lo sí ilé ni eku, òkété òyà, túùpù àti àgbònrín. Òun ni ó sì wá ònà tí wón fi pa Èèmò nípa fífún un ní emu mu tí wón sì jó o mole. Oba: Òun ni ó se ìlérí láti dá ilé àti ònà rè sí méjì tí òun ó sì kó o fún eni tí ó bá lè pa Èèmò. Òun ni ó so fún àwon géńdé pé kí wón lo ki iná bo ilé ti Èèmò ń gbé.

[edit] 13 Omokùnrin kan àti Ìjàpá

Omokùnrin kan wà tí ó jé wí pé nítorí pé òun nìkan ni àwon òbí rè bí, wón ké e ní àkébàjé. Nígbà tí wón bi í pé isé won i yóò se, ó ní isé ode ni. Wón ra, òbúko kan àti àgbò fún un pé kí ó máa fi ofà àti orun ti wón rà fun un se ode lára won. Ó kò jálè, ó ní inú igbó ni òun yóò ti se ode. Ó lo sínú igbó. Ó se ode títí kò rí eran pa. Ó rè é ni ó bá sùn lo. Òjò ńlá rò. Òjò yìí gbé e lo. Ìjàpá rí i, Ìjàpá yo ó nínú omi, ó sì ki omo yìí sí inú ìlù kan. Bí Ìjàpá bá ti lu ìlù yìí ni omo yìí máa ń korin pé, “Réré o, réré o, omo olúwo…À-gbáyùn-ré-ré…Bàbá mérin sílè ó ní n kóde se …………A-gbáyùn-ré-ré… Mo ló digbó efòn, ó digbó erin ……..À-gbáyùn-ré-ré Àgbàrá òjò ló kó mi lésè mo derú Ahun ---------À-gbá yùn-ré-ré. Báyìí ni Ìjàpá se bèrè sí máa lu ìlù yìí ká tí ó sì fi ń pa owó. Kí ó tó di ìgbà yí, àwon òbí omo yìí ti wá omo won títí won kò rí i. Oba pàápàá bá won wá a pèlú. Ó se Ìjàpá lo lu ìlú yìí fún oba léyìn tí oba ti fún un ní àpò owó kan. Oba fetí sí òrò tí ó ń jáde láti inú ìlù yìí. Ó ránsé pe àwon òbí omo yìí. Nígbà tí àwon náà fi etí sí orin omo yìí, wón mò pé omo àwon ni. Oba pàse pé kí wón fa ìlù ya, wón fà á ya, wón sì bá omo yìí níbè. Oba ti kókó fé fi ìyà je Ìjàpá sùgbón nígbà tí ó fi yé won pé se ni òun gba omo náà là nínú àgbàrá òjò, obá dárí jì í, ó sì fún un ní òpòlopò owó àwon òbí yìí sì mú omo won lo sí ilé. Ìtàn yìí kó wa pé kí a má máa ké omo wa ní àkébàjé ó sì kó àwon omodé pé kí won máa gbóràn sí àwon òbó won lénu.

Àwon Èdá-ìtàn Omokùnrin: Òun ni àwon òbí rè ké ní àkébàjé tí ó se ode lo sínú igbó tí Ìjàpá yo jáde nínú omi Ìjàpá: Òun ni ó yo omokùnrin yìí jáde nínú àgbàrá òjò tí ó gbé e sí inú ìlù tí ó sì ń fi ìlù máà pawo Oba: Òun ni ó sàkíyèsí orin tí omo yìí ń ko tí ó ránsé pe àwon òbí rè tí wón fi ráyè yo omo náà kúrò nínú ìlù.

[edit] 14 Ìjàpá àti Olókun

Ìyàn mú púpò ní ìlú Ìjàpá. Oba bèèrè ohun tí wón lè se lówó àwon ará ìlú. Ìjàpá gbà á ní ìmòràn pé kí àwon máa ko òpe kí àwon máa ta epo rè sí ìlú mìíràn kí àwon sì máa gbé oúnje bò láti òhún. Oba gbà ó sì ní kí gbogbo ènìyàn lo se bí Ìjàpá ti wí. Ìjàpá náà lo sí oko rè. Kò rí eyìn tí ó pón. Ààbòn (eyìn tí kò pón) kan soso tí ó rí ní orí ope, bí ó se ní kí òun gé e báyìí ni ó bó sínú òkun. Ìjàpá tèlé e ó sì ń korin pé, òkun gbáàbòn-----Téré ààbòn……” Ibi tí ó ti ń lúwèé tèlé ààbòn yìí ni ó dé ilé Olókun. Olókun bi i ohun tí ó ń wá ó sì sàlàyé fún un. Olókun se ìrànlówó fún un. Ó fún un ní ìgbako kan. Ìgbako yìí sì ń pèsè oúnje fún Ìjàpá tí Ìjàpá bá ti so fún un pé kí ó se isé owó rè. Ìjàpá nìkan ni ó ń dá je oúnje yìí láìfún ìyàwó rè pàápàá je. Ìyàwó lo fi ejó sun oba, oba ránsé pe Ìjàpá ó sì fi agídí mú Ìjàpá fi ìgbako rè bó àwon ènìyàn tí ó wà níbè. Inú Ìjàpá kò dùn sí bí ó se bó gbogbo òpòlopò ènìyàn yìí. Ó lo sí okorè, ó tún lo gé eyìn kan Eyìn yìí ko bó sí inú omi sùgbón ó fi owó ara rè jù ú sínú omi o sì ń lúwèé tèlé e. Ó se, ó dé òdò Olókun. Olókun bi í ohun tí ó ń wa. Ó puró pé eyìn òun ni ó bó sínú omi. Olókun fún un ní ìlagba kan. Nígbà tí Ìjàpá dé ilé tí ó so fún ìlagba pé kí ó isé owó rè, nínà ni ó na Ìjàpá ní ànà-já-sí-sí-méjì tí ó sì tún so ó pò. Ìjàpá mú ìlagba yìí lo sí ààfin ó sì ní kí oba pe àwon ènìyàn jo. Oba se béè, Ìjàpá yí odó borí ó sì ní kí ìlagba se isé owó rè. Ìlagba yìí sì na àwon ènìyàn wònyí. Inú Ìjàpá dùn sùgbón nígbà tí ó máa fid é ilé, igbá rè tí ó ti fi lé orí àjà ti ré bó sílè ó sì ti fó. Báyìí ni òwe àwon àgbà tí ó so pé, “Má bàá mu jadùn, igbó ni eran won ń rá sí” se se sí i lára

Àwon Èdá-ìtàn Oba: Òun ni ó ní kí àwon ará ìlú mú àbá tí wón fi lè ségun ìyàn wá. Ó fi agídí jé kí Ìjàpá wá fi ìgbako rè bó àwon ènìyàn. Òun ni ìlagba Ìjàpá kókó nà ní ànà-já-sí-méjì tí ó sì so ó pò. Ìjàpá: Òun ni ó dábàá ònà tí ìlú fi lè yo nínú ìyàn. Òun ni ó mú ìgbako àti ìlagba wo ìlú tí ó jé kí won se isé owó won. Olókun: Òun ni ó fún Ìjàpá ní ìgbako láti ràn án lówó. Òun náà ni ó fún Ìjàpá ní ìlagba láti fi ìyà je é fún iró tí ó pa nípa eyìn tí kò bó, sí omi tí ó ní ó bó sí omi Yánníbo: Òun ni ó lo so fún Oba nípa ìgbako tí tí Ìjàpá gba bò láti òdò Olókun nírorí pé Ìjàpá kò fún un je lára oúnje tí ìgbako náà ń pèsè.


[edit] 15 Òrìsà-Oko àti Ìjàpá

Ìtàn ní Sókí Àgbè ni Òrìsà-Oko. Ó rí se daadáa. Àgbè náà ni Ìjàpá sùgbón kò rí se. Ìjàpá wá lo bá Òrìsà-Oko pé kí ó ran òun lówó. Òrìsà-Oko gbà láti ràn án lówó. Ó fún Ìjapá ní èso igbá kan, ó ní kí ó gbìn ín sínú oko re sùgbón kí ó rí i wí pé òun wà nínú ààwè odidi ojó kan nígbà tí òun bá ń gbìn ín. Ìjàpá gbin èso igbá sùgbón kò gba ààwè. Nígbà tí igbá yìí so, tí Ìjàpá gé òkan nínú rè, se ni ó bèrè síí lé Ìjàpá ni Ìjàpá bá fi orin sénu pé, “Igbá lÁhun ……..Tere-gúngún-mòjà-gúngún-tere”. Opélopé Àgbò ni ó bá Ìjàpá fi ìwo rè fó igbá yìí. Léyìn ìgbà tí Àgbò ti fo ó tan nì Ìjàpá tún mú èkúfó igbá yìí tí ó fi ń seré. Ibi tí ó ti ń fi seré ni èkúfó igbá yìí ti fò mó on lórùn. Nígbà tí Àgbò kò tún lè ran Ìjàpá lówó mó ni ó bá lo sí òdò Òrìsà-Oko ni oníyan bá fi iná jó èkúfó igbá yìí. Ibi tí ó ti ń jó o ni irun Ìjàpá ti jó. Ìdí nì yí tí Ìjàpá kò fin í irun lórí títí di òní.

Àwon Èdá-ìtàn

Ìjàpá:     Òun ni oko rè kò se dáadáa tí ó lo bèèrè fún ìrànlówó lódò Òrìsà-Oko tí kò sì se ohun tí Òrìsà-Oko ní kí ó se gégé bí ó se ní kí ó se é tí ó sì jìyà sí i.

Òrìsà-Oko: Òun ni ó ran Ìjàpá lówó sùgbón tí Ìjàpá kò se ohun tí ó ní kí ó se gégé bí ó se ní kí ó se é Àgbò: Òun ni ó bá Ìjàpá fó igbá tí ó ń lé e.

[edit] 16 Ìjàpá àti Òbo

Ní ìgbà kan, Ìjàpá pe àwon eranko jo pé òun fé, kí wón bá òun lo sí ilé àna òun. Lára àwon tí ó jé ìpè rè ni Òbo, Agbònrín, Òkèté, Etu, Ikún, Òyà, Ológèdè, Molókò àti Kéké. Òbo gba àwon eranko yìí ni ìmòràn pé kí wón máà bá Ìjàpá lo sùgbón wón kò sí i lénu nítorí náà gbogbo won ni wón lo àfi Òbo nìkan. Ìjàpá sì se ìlérí láti fi ìyà je Òbo fún ìmòràn tí ó gba àwon eranko wònyí`ati lílo tí kò lo. Ní ojó tí wón ń lo, àwon erankó jí wá ni nítorí náà won kò jeun. Ìjàpá nìkan ni ó ti jí jeun. Ní ònà, Ìjàpá so pé Gbogbo-yín ni orúko tí òun yóò máa jé ní ilé àna òun. Nígbà tí wón dé òhún tí wón bá ti gbé oúnje wá tí wón so pé ti gbogbo yín ni, Ìjàpá nìkan yóò dá a je. Báyìí ni Ìjàpá nìkan se dá gbogbo oúnje jet í ebí sì pa àwon yòókù wálé. Nígbà tí wón dé, Ìjàpá lo sí òdò Òbo, ó sì gbàdúrà pé òrò tí a kò mowó tí a kò mesè kí Olórun máà jé kí ó di tiwa. Òbo kò se àmín. Ìjàpá wá lo fi oyin dín àkàrà ó sì fún Ekùn je ní ara rè. Ekùn bi í ibi tí ó, rí nnkan tí ó dùn báyìí. Ìjàpání ìgbé Òbo ni. Ó ní tí Ekùn bá ti rí Òbo kí ó gbá a ní inú dáadáa kí ó so fún un pé kí ń su dídùn. Ekùn se bí Ìjàpá se wí sùgbón bí Ekùn se gbé òbo ní inú tó kò su dídùn ni Ekùn bá fi i sílè. Kò pé léyìn èyí ni Ìjàpá tún lo bá Òbo tí ó se àdúrà tí ó se ní ìjósí. Wéré ni Òbo se àmín. Àmín sì ni Òbo máa ń se títí di òní.

Àwon Èdá-ìtàn Ìjàpá: Òun ni ó be àwon eranko pé kí wón bá òun lo sí ilé àna òun Òbo: Òun ni kò bá Ìjàpá lo sí ilé àna rè. Òun náà ni Ìjàpá jé kí Ekùn fi ìyà je. Ekùn: Òun ni Ìjàpá fún ní àkàrà olóyin. Òun náà ni Ìjàpá lò láti fi ìyà je Òbo. Àgbònrín, Òkété, Etu, Ikún, Òyà, Ológèdè àti Kéké: Àwon ni wón bá Ìjàpá lo sí ilé àna rè ti ìyà sì je won bò láti ibè.

[edit] 17 Kerebújé àti Ìjàpá

Obìnrin tí ó léwà ni Kerebùjé. Gbogbo okùnrin ni ó fé fé e. Ìjàpá náà fé fé e kò sì féé fún un ní kóbò. Ìjàpá lo toro oko lódò okùnrin àgbè kan ní ònà tí Kerebùyé máa ń gba lo sí ojà. Ó pa ejò kan, ó gé orí rè ó sì gbé e sí ònà tí Kerèbùjé yóò gbà. Kerebùjé dé ibi tí ejò wà, ó ké sí àgbè tí ó wà nítòsì láti wá bá òun pa ejò. Ìjàpá jáde, ó se bí eni tí ó pe ejò ó wá fi èjè ejò ra ojúgun. Ó wá bèrè sí korin pé, “Bùjébùjé pAhun o… Kerebùjé”. Ìjàpá ní òun kò lè rìn ni ó wá so pe kí Kerebùjé gbé òun pòn lo sí ilé Oba láti lè bá won yanjú òrò náà. Wón dé ilé Oba, wón ro ejo, Ìjàpá kò jálè láti sò léyìn Kerebùjé. Ó ní òun kò rí ojúgun fi telè. Ó ní ohun tí òun sì ń fé ni pé kí Kerebùjé fé òun kí òun sì wá ònà tí esè òun yóò fi san. Báyìí ni Kerebùjé se di ìyàwó Ìjàpá tí Ìjàpá kò sí ná owó kankan lé e lórí.

[edit] 18 Ìjàpá, Erin àti Erinmilókun

Ní ìgbà kan, Ìjàpá Erin àti Erinmilókun jo ń se òré pò. Nítorí pé ìjàpá kéré jù wón lo, àwon méjèèji ni wón máa ń fi se yèyé. Ìjàpá pinnu láti fi ìyà je wón ó sì fé fi yé won pé òun lágbára ju àwon méjèèjì lo. Ní ojó kan, ó mú okùn kan, ó lo mú un bá Erin. Ó ní kí ó mú apá kan rè dání kí ó fà á tí òun bá tin í kí ó fà á, yóò rí i pé òun Ìjàpá lágbára ju òun lo. Ó mú okùn kan náà lo bá Erinmilókun ó sì so fún un ki ó fa ègbé kejì tí o mú fún un, yóò rí i pé òun Ìjàpá lágbára ju òun lo. Nígbà tí ó ti so báyìí tán fún àwon méjèèjì ni ó bá fa okùn yìí sí òtún àti sí òsì tí ó ní ó yá tí ó sì sá gun igi lo láti máa wòran. Nígbà tí ó pé tí àwon méjèèjì yìí ti ń fi ara won tí kò sí eni tí ó borí òkòòkan nínú won gbà láti wá tuba fún Ìjàpá pé ó lágbára ju òun lo. Wéré, Ìjàpá ti yára sòkalè lórí igi, ó gé okùn yìí sí méjì, ó sì mú un dání ní òkòòkan láti fi hàn pé owó kan ni òun fi ń fa Erin, owó kan ni òun sì fi ń fa Erinlókun. Nígbà tí àwon méjèèjì rí Ìjàpá wón túúbá fún un, wón sì gbà á ní alágbára

Ohun tí Ìtàn yìí ko wa Ìtàn yìí kó wa pé kí a má máa fi omodé se yèyé àti pé alágbára má mèrò ni baba òle.

[edit] 19 Erin àti Ìjàpá

Nïgbà kan, Erin ń da ìlú kan láàmú oba sì pe gbogbo ará ìlú jo láti wá eni ti yóò bá àwon mú un. Obá sèlérí pé òun yóò dá ilé àti ònà òun sí méjì fún eni tí ó bá lè bá àwon ségun rè. Ìjàpá so fún oba pé òun yóò lo. Ó gbé ìlù rè, ó lo sí ibi tí Erín wà, ó sì ń korin fún pé “A ó mérin joba……Èrèkú-ewele”. Rí Ìjàpá tó kúrò ní ìlú, ó tin í kí won gbe ihò ńlá kan sílè kí wón sì té ení tí ó dára lé e lórí. Ibi ihò yìí ni Ìjàpá ń mú Erin lo. Bí ó ti kù díè kí Erin dé ibi ihò yìí ni eye kan ń korin fún un pé “Erin o…..Ìwòyí òla re, Agada á se féré, Èjè á ru bàlà”. Nígbà tí Erin gbó orin eye yìí, ó kókó fé kò láti máa lo sùgbón nígbà tí àwon onílù àti sèkèrè tún lù sí i ó ní ìdí ó gbà láti jókòó lé ori ení náà. Bí ó se jókòó lé orí ení yìí ni ó jìn sí kòtò tí àwon géńdé sì lùú pa. Báyìí ni Erin se fi àìgbó ohun tí eyé fi orin se fún un pa ara rè. Oba sì dá ilé àti ònà sí méjì ó sì kó o fún Ìjàpá.

[edit] 20 Ìjàpá àti àwon Omo-ìyá méta

Àwon omo-ìyá méta kan wà tí òbí won ti kú tí wón sì máa ń lo sí òdò Ìjàpá láti gba ìmòràn. Ní ìgbà kan, wón lo bá Ìjàpá láti gba àwon ní ìmòràn lórí isé tí àwon lè se. Ìjàpá gbà wón ní ìmòràn láti wá máa bá òun sisé pò. Léyìn ìgbà tí àwon omo ti ronú lórí ìmòràn Ìjàpá, wón rán-ègbón won sí i láti lè so fún un pé àwon kò lè bá a sisé pò nítorí pé bí olè bí àfowórá ni isé tí Ìjàpá ń se. Isé ti wón ni àwon kò lè bá a se yìí bí Ìjàpá nínú púpò. Létìn tí wón ti kò sí Ìjàpá lénu tán ni wón ti pàrò pò tí èyí ègbón ti gbà láti se isé òpe kíko, èyí èkèjì ní òun yóò wa okò ojú omi, èyí èkéta sì gbà láti máa fi ofà se ode. Ìjàpá lo bá Oba ó sì kó bá àwon omo yìí. Ó ní òkan nínú won (Ó pè wón níjàndùkú) ní òun lè fi owó lásán gun igi àgbon èkéjì ní òun yóò we òkun, èkéta sì ní òun yóò ta òrun Obá ránsé pe àwon omo yìí láìgbó tenu won, ó pàse fún won pé kí wón se ohun tí Ìjàpá ní won yóò se. Ó fún won ní ojó méje láti se é. Nígbà tí àwon omo yìí dé ilé, ìyá won tí ó ti kú yí ara padà ó di eye, ó fún omo rè tí yóò gun àgbon ní igbà ti àwon ènìyàn kò lè rí láti fi gun àgbon. Ó fún èyí tí yóò we òkun ní ìbànté ó sì fún èyí tí yóò ta òrun ní ofà. Báyìí ni àwon omo yìí lo hunt í eye yìí fún won tí èyí tí ó jé ègbón gun òpe, èyí tí ó tèlé e we òkun ja tí èyí àbúrò sì ta òrun Orin tí eye yìí ń ko ni “Omodé méta ń seré………Eré o, é …….Eré ayò, Òkan lóun ó gagbon…………….Eré o, é ………Eré ayò……” Báyìí ni àwon omo yìí lo àwon ohun ti eye yìí fún won tí èyí tí ó jé ègbón gun àgbon, èyí tí ó tèlé e we òkun ja èyí tí ó sì kéré ju ta òrun. Oba ní kí wón pa Ìjàpá ó sì dá ilé àti ònà rè sí méjì, ó kó o fún àwon omo yìí.

Our "Network":

Project Gutenberg
https://gutenberg.classicistranieri.com

Encyclopaedia Britannica 1911
https://encyclopaediabritannica.classicistranieri.com

Librivox Audiobooks
https://librivox.classicistranieri.com

Linux Distributions
https://old.classicistranieri.com

Magnatune (MP3 Music)
https://magnatune.classicistranieri.com

Static Wikipedia (June 2008)
https://wikipedia.classicistranieri.com

Static Wikipedia (March 2008)
https://wikipedia2007.classicistranieri.com/mar2008/

Static Wikipedia (2007)
https://wikipedia2007.classicistranieri.com

Static Wikipedia (2006)
https://wikipedia2006.classicistranieri.com

Liber Liber
https://liberliber.classicistranieri.com

ZIM Files for Kiwix
https://zim.classicistranieri.com


Other Websites:

Bach - Goldberg Variations
https://www.goldbergvariations.org

Lazarillo de Tormes
https://www.lazarillodetormes.org

Madame Bovary
https://www.madamebovary.org

Il Fu Mattia Pascal
https://www.mattiapascal.it

The Voice in the Desert
https://www.thevoiceinthedesert.org

Confessione d'un amore fascista
https://www.amorefascista.it

Malinverno
https://www.malinverno.org

Debito formativo
https://www.debitoformativo.it

Adina Spire
https://www.adinaspire.com